Barack Obama

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Barack Obama
U.S. President Barack Obama is photographed standing in front of the Resolute Desk in the Oval Office of the White House, December 6, 2012.
44th Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
Lọ́wọ́
Ó bọ́ sí orí àga
Oṣù Kínní 20, 2009 (2009-01-20)
Vice President Joe Biden
Asíwájú George W. Bush
United States Senator
from Illinois
Lórí àga
Oṣù Kínní 3, 2005 (2005-01-03) – Oṣù Kọkànlá 16, 2008 (2008-11-16)
Asíwájú Peter Fitzgerald
Arọ́pò Roland Burris
Member of the Illinois Senate
from the 13th District
Lórí àga
January 8, 1997 – November 4, 2004
Asíwájú Alice Palmer
Arọ́pò Kwame Raoul
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ìbí Barack Hussein Obama II
Oṣù Kẹjọ 4, 1961 (1961-08-04) (ọmọ ọdún 54)
Honolulu, Hawaii, U.S.
Ẹgbẹ́ olóṣèlú Democratic
Tọkọtaya pẹ̀lú Michelle Robinson (m. 1992–present) «start: (1992)»"Marriage: Michelle Robinson to Barack Obama" Location:Àdàkọ:Placename/adr (linkback://yo.wikipedia.org/wiki/Barack_Obama)
Àwọn ọmọ Malia (b. 1998)
Sasha (b. 2001)
Ibùgbé White House (official)
Chicago, Illinois (private)
Alma mater Occidental College
Columbia University (B.A.)
Harvard Law School (J.D.)
Profession Community organizer
Lawyer
Constitutional law professor
Author
Ẹ̀sìn Christian
Awards Nobel Peace Prize
Ìtọwọ́bọ̀wé Barack Obama
Website barackobama.com

Barack Hussein Obama Jr. (ojoibi 4 August, 1961) je oloselu ati Aare orile-ede ile Amerika. A bí Barack Obama ní ọjó ìkérin, oṣù èkéjọ (ògún), odún 1961. Ó jé òṣèlú orílè èdè Améríkà, ọmọ ilé ìgbìmó aṣòfin láti ìpínlè Illinois, ọmọ ẹgbé òṣèlú Democrat. Barack Obama jé òkan nínú àwọn òṣèlú méjì tí wón figa gbága láti je Àrẹ ilè Amerika. Ẹni èkejì ni John Mccain. Ni ojo kerin osu kokanla odun 2008 Obama wole ibo fun ipo Aare ile Amerika. Obama gori oye ni ogun jo osu kinni odun 2009. Barack Obama jé ènìyàn dúdú àkọ́kọ́ tí òkan nínú àwọn egbé òṣèlú nlá ti ilè Amerika fún ní ànfàní láti kóra nínú eré ìje àti di Ààrẹ ilè Amerika láti ẹgbẹ́ òṣèlú Demokratiki.

Igbesiaye[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wón bí Barack Obama ní ìlú Honolulu, ìpínlè Hawaii ní ọdun 1961. Àwòn òbí ré rí ara won ní ìgbà tí wón nka ìwé ní ilé èkó Unifasiti Hawaii ní ìlu Manoa. Bàba rè wá láti orílè èdè Kenya. Barack Hussein Obama- àgbà, lọ ka ìwé nípa òrò ajé ní ilè Amerika. Ìya rè, ènìyàn funfun, ọmọ ilè Amerika, Stanley Ann Dunham, jé ọmọ ilé èkó Unifasiti láti ìlu Wichitta, ìpínlè Kansas. Àwọn òbí ìya rè lòdì sí àjọṣe àwọn méjèjì, ṣùgbón wón fé ara wọn ní ọdun 1960. Ọdún méjì léhìn tí wón bí Obama, bàbá rè lọ si Howard fún ìtèsíwájú èkọ rè, ṣùgbón kò mú ẹbí rè lọ nítorí àìsí owó. Ní àìpé ọjó wón yapa. Ní ìgbà èkó rè ní Howard, Obama- àgbà fé Ruth Nidesand, ẹni tí ó bá padà sí orílè èdè Kenya léhìn ìparí èkò rè. Ruth Nidesand jé ìyàwó rè ẹ̀kẹ́ta, wón sì ní ọmọ méjì. Ní orílè èdè Kenya, Obama- àgbà bèrè iṣé ní ilé iṣé tí ó nwa epo ròbì, léhìn èyí, ó ṣiṣé fún ìjọba, gégébí olóòtú ètò ọrò ajé. Ó fi ojú kan ọmọ rè, Obama, ní ìgbàkan péré- ní ìgbà tí oní tòhún pé ọmọ ọdún méwàá. Obama- àgbà fi arapa nínú àgbákò ọkò nípa èyí tí ó sọ ẹsè méjèjì nù. Ní ìgbà tí ó pé ọmọ ọdún mérin-dí-láàdóta, ní ọdún 1982, ó sọ èmí rè nù nínú àgbákò ọkò.

Léhìn ìyapa pèlu bàba Obama, ìya rè fé Lolo Soetoro, ọmọ ilé èkó gíga unifasiti láti orílè èdè Indonesia. Ní ọdún 1967 ó sì bá Lolo Soetoro lọ sí Indonesia. Barack Obama ní ọbàkàn, obìnrin, ọmọ Lolo àti Stanley Ann. Stanley Ann Dunham pèhìndà ní ọdún 1995.

Barack àti ìyàwọ́ rẹ̀ Michelle Obama



Ìwé tó kọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Obama, Barack. Dreams from My Father: A Story of Race and Inheritance, Times Books, 1995. Reprint edition, 2004; ISBN 1-4000-8277-3
  • Obama, Barack. The Audacity of Hope: Thoughts on Reclaiming the American Dream, Crown, 2006. ISBN 0-307-23769-9.


Àwọn ibùdó lori Interneti[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wikinews-logo.svg
Wikinews ní ìròhìn lórí ọ̀rọ̀ yíì:


Wikiquote logo
Nínú Wikiquote a ó rí ọ̀rọ̀ tójẹmọ́:
Wikisource-logo.svg
Wikisource has original text related to this article:

Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]